Oludije funpo ile igbimọ aṣofin agba lati Ila-Oorun Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ Accord, Hon. Ibukun Fadipẹ, ti wọ ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, Olatunji Disu, igbakeji rẹ lẹkun kọkanla, Kọmiṣanna ọlopaa l'Ọṣun, Senetọ Francis Adenigba Fadahunsi atawọn miin, lọ si kootu bayii.
Fadipẹ ni awọn olujẹjọ ọhun tẹ ẹtọ oun labẹ ofin loju mọlẹ, nitori naa, o beere fun miliọnu lọna aadọta naira lọwọ wọn.
Ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Oṣogbo ni Fadipẹ gbe awọn eeyan naa lọ ninu iwe ipẹjọ to ni nọmba FHC/OS/144/2026.
Gẹgẹ bi awọn agbẹjọro fun Fadipẹ, eleyii ti Amofin Bukọla Onifade ko sodi, ṣe sọ, igbesẹ naa ko ṣẹyin iwa fitina igba gbogbo, didunkoko mọni ati ikọlu ojukoroju ti awọn olujẹjọ hu si olupẹjọ laaarin ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Keje si ọjọ Kọkanlelọgbọn, oṣu Keje ọdun yii.
Fadipẹ fẹsun kan Sẹnetọ Fadahunsi, ẹni to jẹ oludije funpo ile igbimọ aṣofin agba lati Ila-Oorun Ọṣun ninu ẹgbẹ APC, pe o n lo awọn ọlọpaa atawọn tọọgi oloṣelu lati daamu oun. O ni lọgbọnjọ oṣu Keje ọdun yii ni ọrọ naa tun lagbara sii nigba ti ọmọọṣẹ Fadahunsi, iyẹn Solomon Wẹmimọ to jẹ olujẹjọ karun-un ko awọn ọlọpaa atawọn tọọgi ẹgbẹ APC lati ba ọfiisi ipolongo ibo oun ni Ileṣa jẹ, ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia jẹ nibẹ.
Olupẹjọ ṣalaye pe, lọwọlẹsẹ lo ku ti awọn olujẹjọ yii n ṣọ oun kaakiri, eyi to si ti mu ifasẹyin ba iṣẹ oojọ oun, oun ko le rin bo ṣe wu oun, bẹẹ ni oun ko lanfaani lati polongo ibo ṣaaju idibo apapọ oṣu Keji, ọdun to n bọ.
Agbẹjọro Fadipẹ lo abala ikẹrinlelọgbọn ofin orileede Naijiria ti ọdun 1999, eyi ti wọn ṣatunṣe si lọdun 2023, ninu eyi ti aabo ti wa fun araalu lọwọ idunkokomọni lọnakọna, lati fi gbe ara rẹ lẹsẹ.
O ni abala ikọkanlelogoji ofin naa fun awọn ọmọ Naijiria laaye lati rin bo ṣe wu u kaakiri lorileede yii, bẹẹ ni abala ikẹtalelogoji faaye gba araalu lati ni dukia, ninu rẹ naa si ni ọfiisi ipolongo ibo ati iṣẹ oojọ lai si ẹnikẹni ti yoo halẹ mọ ọn.
Bakan naa lo ni abala ikẹrindinlaadọta ofin naa faaye gba ẹni ti wọn ba tẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ lati lọ si kootu.
Lara ẹbẹ ti Fadipẹ gbe lọ ni pe ki kootu sọ pe ohun ti ko bofin mu ni bi awọn ọlọpaa ṣe n fojoojumọ ranṣẹ si i ati bi wọn ṣe n halẹ lati fi pampẹ ofin gbe e.
O ni ki kootu paṣẹ pe wọn ko gbọdọ ti i mọle, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ daamu rẹ mọ, ati pe wọn ko gbọdọ da ominira rẹ lati lọ kaakiri fun ipalẹmọ idibo duro rara.
O beere fun miliọnu lọna aadọta naira lọwọ awọn olujẹjọ, bẹẹ lo ni ki wọn tọrọ aforijin lọwọ oun ninu iwe iroyin ilẹ wa meji.

No comments:
Post a Comment